ÌKÌLỌ̀ FÚN ÀWỌN OLÙDÓKÒWÒ — FÍFI OJÚ-ÒPÓ ÌṢÒWÒ AYÉLUJÁRA ILẸ̀ ÍTÁLÌ MÁRÙN-ÚN (5) SÓRÍ ÀKỌSÍLẸ̀ DÚDÚ Tí a tẹ̀ jáde: March 30, 2023
22/03/2023
Aláṣẹ àbójútó ìwé ìdókòwò ilẹ̀ Ítálì, (Commissione Nazionale per le Soecieta’ e la Borsa – CONSOB) ti fi ojú-òpó ìṣòwò ayélujára márùn-ún (5) míì sórí àkọsílẹ̀ dúdú nítorí wọ́n ń pèsè iṣẹ́ ìṣúná tí kò ní àṣẹ, tí ó sì jẹ́ ti ìjìbìtì. Àwọn ojú-òpó náà ni:
- CMS Ltd (capmarketstrategy.io, pẹ̀lú ojú-òpó rẹ̀ https://client.capmarketstrategy.io);
- Bitsterzio(https://www.bitsterzio.com);
- Invest Atlas (https://investatlas.co)
- Ether-Arena Ltd (www.ether-arena.com); àti
- Ether-Arena Ltd (https://veneab.co, pẹ̀lú ojú-òpó rẹ̀: https://clientzone,vineab.com ).
CONSOB pàṣẹ fún Àwọn Olùpèsè Iṣẹ́ Ayélujára (ISP) tí ń ṣiṣẹ́ ní Ítálì láti dí ọ̀nà tí gbogbo ènìyàn fi lè wọ àwọn ojú-òpó tí a fi sórí àkọsílẹ̀ dúdú. Ó tún pe àwọn tí wọ́n fẹ́ dókòwò láti ṣọ́ra gidigidi nígbà tí wọ́n bá ń yan ìdókòwò, kí wọ́n sì ṣe àwọn ìgbésẹ̀ tó bógbọ́n mu láti dáàbò bo owó ìpamọ́ wọn, títí kan ṣíṣàyẹ̀wò bóyá àwọn ojú-òpó ìṣòwò ayélujára bẹ́ẹ̀ ní ìforúkọsílẹ̀ tàbí kò ní í ṣe.
Ìgbìmọ̀ náà tún fẹ́ pe àfiyèsí àwọn olùdókòwò Nàìjíríà sí i pé SEC Nigeria kò forúkọ àwọn ojú-òpó ìṣòwò ayélujára tí a darukọ lókè sílẹ̀, SEC kò sì fún àwọn iṣẹ́ ìṣúná tí wọ́n ń pèsè ní àṣẹ.
Nítorí èyí, a ń KILỌ̀ fún gbogbo ènìyàn pé ẹnikẹ́ni tí ó bá bá àwọn ojú-òpó ìṣòwò ayélujára tí a darukọ lókè ṣe ìdúnàdúrà ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní eewu tirẹ̀.
FỌWỌ́ SÍ I
ÌṢÀKÓSO